17
Ní Tẹsalonika
1 Nígbà tí wọn sì ti kọjá Amfipoli àti Apollonia, wọ́n wá sí Tẹsalonika, níbi tí Sinagọgu àwọn Júù wà. 2 Àti Paulu, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́. 3 Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.” 4 A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila, bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀.
5 Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn sì fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ènìyàn mọ́ra, wọ́n ko ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jasoni, wọ́n ń fẹ́ láti mú Paulu àti Sila jáde tọ àwọn ènìyàn lọ. 6 Nígbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jasoni, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò títí de ìhín yìí pẹ̀lú. 7 Àwọn ẹni tí Jasoni gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kesari, wí pé, ọba mìíràn kan wà tí í ṣe Jesu.” 8 Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí. 9 Nígbà tí wọ́n sì gbà onídùúró lọ́wọ́ Jasoni àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ lọ.
Ní Berea
10 Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Paulu àti Sila lọ ṣí Berea lóru. Nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ. 11 Àwọn Júù Berea sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalonika lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì ń wá inú ìwé mímọ́ lójoojúmọ́ bí nǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀. 12 Nítorí náà púpọ̀ nínú wọn gbàgbọ́; àti nínú àwọn obìnrin Giriki ọlọ́lá, àti nínú àwọn ọkùnrin ti kì í ṣe díẹ̀.
13 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù tí Tẹsalonika mọ̀ pé, Paulu ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Berea, wọ́n wá síbẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n rú àwọn ènìyàn sókè. 14 Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Paulu jáde lọ́gán láti lọ títí de etí Òkun, ṣùgbọ́n Sila àti Timotiu dúró ní Berea. 15 Àwọn tí ó sin Paulu wá sì mú un lọ títí dé Ateni; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sila àti Timotiu pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.
Ní Ateni
16 Nígbà tí Paulu dúró dè wọ́n ni Ateni, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà. 17 Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sinagọgu, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́. 18 Nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Epikure ni àti tí àwọn Stoiki kó tì í. Àwọn kan si ń wí pé, “Kín ni aláhesọ yìí yóò rí wí?” Àwọn mìíràn sì wí pé, “Ó dàbí oníwàásù àjèjì òrìṣà, wọ́n sọ èyí nítorí Paulu ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu àti àjíǹde fún wọn.” 19 Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fà á lọ sí Areopagu, wọ́n wí pé, “A ha lè mọ̀ kín ni ẹ̀kọ́ tuntun tí ìwọ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́? 20 Nítorí tí ìwọ mú ohun àjèjì wá sí etí wa, àwa sì ń fẹ́ mọ̀ kín ni ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí.” 21 Nítorí gbogbo àwọn ará Ateni, àti àwọn àjèjì tí ń ṣe àtìpó níbẹ̀ kì í ṣe ohun mìíràn jù kí a máa sọ tàbí kí a máa gbọ́ ohun tuntun lọ.
22 Paulu si dìde dúró láàrín Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Ateni, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún ẹ̀sìn lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 23 Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí sí:
Fún Ọlọ́run àìmọ̀.
Ǹjẹ́ ẹni tí ẹ̀yin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń sọ fún yin.
24 Isa 42.5.“Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé tẹmpili tí a fi ọwọ́ kọ́. 25 Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn. 26 Ó sì tí tipasẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn; 27 Ọlọ́run ṣe eléyìí kí wọn bá le máa wa, bóyá wọn yóò lè ṣàfẹ́rí rẹ̀, kí wọn sì rí í. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa. 28 Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láààyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa, bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkára yín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’
29 “Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, ẹni tí a wa n sìn dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya ère àwòrán rẹ̀. 30 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí fojú fò dá; ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà. 31 Níwọ́n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípasẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, ní ti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú.”
32 Nígbà tí wọ́n ti gbọ́ ti àjíǹde òkú, àwọn mìíràn ń ṣẹ̀fẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn wí pé, “Àwa o tún nǹkan yìí gbọ́ lẹ́nu rẹ̀.” 33 Bẹ́ẹ̀ ni Paulu sì jáde kúrò láàrín wọn. 34 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin kan fi ara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́: nínú àwọn ẹni tí Dionisiu ara Areopagu wà, àti obìnrin kan tí a ń pè ni Damari àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn.