18
Wọ́n mú Jesu
Mt 26.30,36; Mk 14.26,32; Lk 22.39; 2Sa 15.23.Nígbà tí Jesu sì ti sọ nǹkan wọ̀nyí tán, ó jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sókè odò Kidironi, níbi tí àgbàlá kan wà, nínú èyí tí ó wọ̀, Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
Judasi, ẹni tí ó fihàn, sì mọ ibẹ̀ pẹ̀lú, nítorí nígbà púpọ̀ ni Jesu máa ń lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Mt 26.47-56; Mk 14.43-50; Lk 22.47-53.Nígbà náà ni Judasi, lẹ́yìn tí ó ti gba ẹgbẹ́ ọmọ-ogun, àti àwọn oníṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi wá síbẹ̀ ti àwọn ti fìtílà àti ògùṣọ̀, àti ohun ìjà.
Jh 6.64; 13.1.Nítorí náà bí Jesu ti mọ ohun gbogbo tí ń bọ̀ wá bá òun, ó jáde lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni ẹyin ń wá?”
Wọ́n sì dá a lóhùn wí pé, “Jesu ti Nasareti.”
Jesu sì wí fún wọn pé, “Èmi nìyí.” (Àti Judasi ọ̀dàlẹ̀, dúró pẹ̀lú wọn). Nítorí náà bí ó ti wí fún wọn pé, “Èmi nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀.
Nítorí náà ó tún bi wọ́n léèrè, wí pé, “Ta ni ẹ ń wá?”
Wọ́n sì wí pé, “Jesu ti Nasareti.”
Jesu dáhùn pé, “Mo ti wí fún yín pé, èmi nìyí. Ǹjẹ́ bí èmi ni ẹ bá ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ.” Jh 17.12; 6.39.Kí ọ̀rọ̀ nì kí ó lè ṣẹ, èyí tó wí pé, “Àwọn tí ìwọ fi fún mi, èmi kò sọ ọ̀kan nù nínú wọn.”
10 Nígbà náà ni Simoni Peteru ẹni tí ó ní idà, fà á yọ, ó sì ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ké etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù. Orúkọ ìránṣẹ́ náà a máa jẹ́ Makọọsi.
11  Mk 10.38; 14.36.Nítorí náà Jesu wí fún Peteru pé, “Tẹ idà rẹ bọ inú àkọ̀ rẹ, ago tí baba ti fi fún mi, èmi ó ṣe aláìmu ún bí?”
Jesu níwájú Annasi
12  Mt 26.57; Mk 14.53; Lk 22.54; 3.2.Nígbà náà ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀ṣọ́, àti àwọn oníṣẹ́ àwọn Júù mú Jesu, wọ́n sì dè é. 13 Wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Annasi; nítorí òun ni àna Kaiafa, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà. 14  Jh 11.49-51.Kaiafa sá à ni ẹni tí ó ti bá àwọn Júù gbìmọ̀ pé, ó ṣàǹfààní kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn.
Peteru sẹ́ Jesu ní àkọ́kọ́
15  Mt 26.58; Mk 14.54; Lk 22.54.Simoni Peteru sì ń tọ Jesu lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jesu wọ ààfin olórí àlùfáà lọ. 16 Ṣùgbọ́n Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùṣọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Peteru wọlé.
17  Mt 26.69-72; Mk 14.66-69; Lk 22.56-58.Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà wí fún Peteru pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?”
Ó wí pé, “Èmi kọ́.”
18 Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn aláṣẹ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí ti òtútù mú, wọ́n sì ń yáná, Peteru sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.
Alábojútó àlùfáà fi ọ̀rọ̀ wá Jesu lẹ́nu wò
19  Mt 26.59-66; Mk 14.55-64; Lk 22.67-71.Nígbà náà ni olórí àlùfáà bi Jesu léèrè ní ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ní ti ẹ̀kọ́ rẹ̀.
20 Jesu dá a lóhùn pé, “Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sinagọgu, àti ní tẹmpili níbi tí gbogbo àwọn Júù ń péjọ sí, èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀. 21  Èéṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè? Béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ohun tí mo wí fún wọn: wò ó, àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí èmi wí.”
22 Bí ó sì ti wí èyí tan, ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ tí ó dúró tì í fi ọwọ́ rẹ̀ lu Jesu, pé, “Alábojútó àlùfáà ni ìwọ ń dá lóhùn bẹ́ẹ̀?”
23  Mt 5.39; Ap 23.2-5.Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá sọ̀rọ̀ búburú, jẹ́rìí sí búburú náà, ṣùgbọ́n bí rere bá ni, èéṣe tí ìwọ fi ń lù mí?” 24  Jh 18.13; Lk 3.2.Nítorí Annasi rán an lọ ní dídè sọ́dọ̀ Kaiafa olórí àlùfáà.
Peteru sẹ́ Jesu ní ìgbà kejì àti ìgbà kẹta
25  Mt 26.73-75; Mk 14.70-72; Lk 22.59-62.Ṣùgbọ́n Simoni Peteru dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?”
Ó sì sẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.”
26 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Peteru gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?” 27 Peteru tún sẹ́: lójúkan náà àkùkọ sì kọ.
Jesu níwájú Pilatu
28  Jh 11.55; Mt 27.1-2; Mk 15.1; Lk 23.1.Nígbà náà, wọ́n fa Jesu láti ọ̀dọ̀ Kaiafa lọ sí ibi gbọ̀ngàn ìdájọ́, ó sì jẹ́ kùtùkùtù òwúrọ̀; àwọn tìkára wọn kò wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́, kí wọn má ṣe di aláìmọ́, ṣùgbọ́n kí wọn lè jẹ àsè ìrékọjá. 29  Mt 27.11-14; Mk 15.2-5; Lk 23.2-3.Nítorí náà Pilatu jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí pé, “Ẹ̀sùn kín ní ẹ̀yin mú wá fun ọkùnrin yìí?”
30 Wọ́n sì dáhùn wí fún un pé, “Ìbá má ṣe pé ọkùnrin yìí ń hùwà ibi, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́.”
31 Nítorí náà Pilatu wí fún wọn pé, “Ẹ mú un tìkára yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin yín.”
Nítorí náà ni àwọn Júù wí fún un pé, “Kò tọ́ fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.” 32  Jh 3.14; 12.32.Kí ọ̀rọ̀ Jesu ba à lè ṣẹ, èyí tí ó sọ tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.
33 Nítorí náà, Pilatu tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jesu, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ha ni a pè ni ọba àwọn Júù bí?”
34 Jesu dáhùn pé, “Èrò ti ara rẹ ni èyí, tàbí àwọn ẹlòmíràn sọ ọ́ fún ọ nítorí mi?”
35 Pilatu dáhùn wí pé, “Èmi ha jẹ́ Júù bí? Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ, àti àwọn olórí àlùfáà ni ó fà ọ́ lé èmi lọ́wọ́, kín ní ìwọ ṣe?”
36  Jh 6.15; Mt 26.53.Jesu dáhùn wí pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Ìbá ṣe pé ìjọba mi jẹ́ ti ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ìbá jà, kí a má ba à fi mí lé àwọn Júù lọ́wọ́, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba mi kì í ṣe láti ìhín lọ.”
37  Jh 3.32; 8.14,47; 1Jh 4.6.Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Ọba ni ọ́ nígbà náà?”
Jesu dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.”
38  Mt 27.15-26; Mk 15.6-15; Lk 23.18-19; Ap 3.14.Pilatu wí fún un pé, “Kín ni òtítọ́?” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀. 39 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní àṣà kan pé, kí èmi dá ọ̀kan sílẹ̀ fún yín nígbà àjọ ìrékọjá, nítorí náà ẹ ó ha fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?”
40 Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Baraba!” Ọlọ́ṣà sì ni Baraba.

18:1 Mt 26.30,36; Mk 14.26,32; Lk 22.39; 2Sa 15.23.

18:3 Mt 26.47-56; Mk 14.43-50; Lk 22.47-53.

18:4 Jh 6.64; 13.1.

18:9 Jh 17.12; 6.39.

18:11 Mk 10.38; 14.36.

18:12 Mt 26.57; Mk 14.53; Lk 22.54; 3.2.

18:14 Jh 11.49-51.

18:15 Mt 26.58; Mk 14.54; Lk 22.54.

18:17 Mt 26.69-72; Mk 14.66-69; Lk 22.56-58.

18:19 Mt 26.59-66; Mk 14.55-64; Lk 22.67-71.

18:23 Mt 5.39; Ap 23.2-5.

18:24 Jh 18.13; Lk 3.2.

18:25 Mt 26.73-75; Mk 14.70-72; Lk 22.59-62.

18:28 Jh 11.55; Mt 27.1-2; Mk 15.1; Lk 23.1.

18:29 Mt 27.11-14; Mk 15.2-5; Lk 23.2-3.

18:32 Jh 3.14; 12.32.

18:36 Jh 6.15; Mt 26.53.

18:37 Jh 3.32; 8.14,47; 1Jh 4.6.

18:38 Mt 27.15-26; Mk 15.6-15; Lk 23.18-19; Ap 3.14.