16
Ìdáhùn Jobu fún Elifasi
1 Ìgbà náà ní Jobu dáhùn, ó sì wí pé,
2 “Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí
ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín.
3 Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin?
Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn?
4 Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin;
bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi,
èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn,
èmi a sì mi orí mi sí i yín.
5 Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú,
àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.
6 “Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ;
bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí ko kúrò?
7 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara;
ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.
8 Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí;
àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú.
9 Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí;
ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi,
ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.
10 Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi;
Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn;
wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.
11 Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú,
ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.
12 Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já;
ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú,
ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe àmì ìtafàsí rẹ̀;
13 àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri.
Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí,
ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.
14 Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;
ó súré kọlù mi bí jagunjagun.
15 “Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi,
mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
16 Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún,
òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.
17 Kì í ṣe nítorí àìṣòótọ́ kan ní ọwọ́ mi;
àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú.
18 “Háà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi,
kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan.
19 Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run,
ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run.
20 Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín,
ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run,
21 ìbá ṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
bí ènìyàn kan ti í ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀.
22 “Nítorí nígbà tí iye ọdún díẹ̀ rékọjá tán,
nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.”