6
Ọ̀rẹ́
1 Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,
ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?
Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,
kí a lè bá ọ wá a?
Olólùfẹ́
2 Olùfẹ́ mi ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀,
sí ibi ibùsùn tùràrí,
láti máa jẹ nínú ọgbà
láti kó ìtànná lílì jọ.
3 Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi,
Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì.
Olùfẹ́
4 Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tirsa,
ìwọ lẹ́wà bí i Jerusalẹmu,
ìwọ ògo bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.
5 Yí ojú rẹ kúrò lára mi;
nítorí ojú rẹ borí mi.
Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́
tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gileadi.
6 Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn,
tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá,
gbogbo wọn bí ìbejì,
kò sì ṣí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.
7 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bàá ìbòjú rẹ,
rí bí ẹ̀là èso pomegiranate.
8 Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀,
àti ọgọ́rin àlè,
àti àwọn wúńdíá láìníye.
9 Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni,
ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀,
ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i.
Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún
àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un.
Ọ̀rẹ́
10 Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀,
tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn,
tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?
Olùfẹ́
11 Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi
láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì,
láti rí i bí àjàrà rúwé,
tàbí bí pomegiranate ti rudi.
12 Kí èmi tó mọ̀,
àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàrín àwọn ènìyàn mi.
Ọ̀rẹ́
13 Padà wá, padà wá, ìwọ ọmọ Ṣulamati;
padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò.
Olùfẹ́
Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣulamati wò,
bí ẹni pé orin ijó Mahanaimu?